HYMN 1

C.M.S. 1, H.C. 2, L.M. (FE 19)
"Emi tikara mi yio ji ni kutukutu" - Ps 108:2


1. Ji, okan mi, ba orun ji 

   Mura si ise ojo re; 

   Mase ilora, ji kutu, 

   K’o san gbese ebo oro.


2. Ro gbogbo ojo t‘o fi sofo 

   Bere si rere ‘se loni,

   Kiyes' irin re laiye yi; 

   K'o si mura d‘ojo nla ni.


3. K’oro re gbogbo j'otito 

   K'okan re mo b‘osan gangan 

   Mo p'Olorun nso ona re

   O mo ero ikoko re.


4. Gba ninu imole orun 

   Si tan ‘mole na f'elomi 

   Jeki ogo Olorun re,

   Han n’nu wa ati ise re.


5. Ji, gbon‘ra nu ‘ wo okan mi 

   Yan ipo re larin Angel 

   Awon ti nwon nkorin iyin 

   Ni gbogbo oru s’Oba wa.


6. Mo ji, mo ji, ogun orun

   Ki isin yi s‘okan mi ji

   Ki nle lo ojo aye mi 

   Fun Olorun mi bi ti yin. Amin

English »

Update Hymn