HYMN 10

C.M.S 18, H.C 24, t.H.C 99 10s. (FE 27)
"Ngo dide, ngo to Baba mi la" - Luku 15:18


1. Baba, a tun pade l'oko Jesu,

   A si wa teriba lab‘ese Re;

   A tun fe gb‘ohun wa soke si O, 

   Lati wa anu Iati korin 'yin.


2. A yin O fun itoju ‘gba gbogbo 

   Ojojumo l'a ma rohin se Re, 

   Wiwa laye wa, anu Re ha ko? 

   Apa Re ki O fi gba ni mora?


3. O se! a ko ye fun ife nla Re,

   A sako kuro Iodo Re poju 

   Sugbon kikankikan ni O si npe; 

   Nje, a de, a pada wa ‘le, Baba.


4. Nipa oko t‘o bor‘ohun gbogbo 

   Nipa ife t'o ta 'fe gbogbo yo, 

   Nipa eje ti a ta fun ese,

   Silekun anu, si gbani s'ile. Amin

English »

Update Hymn