HYMN 104

1. Fl iyin fun! Jesu, Olurapada wa

   Ki aiye k'okiki ire Re nla

   Fi iyin fun! enyin Angeli ologo

   F'ola at‘ogo fun oruko Re

   B'Olusaguntan, Jesu y'o to omo Re

   L'aoa Re lo ngbe won le lojojo

   Enyin eniyan mimo ti ngb‘oke Sion

   Fi iyin fun pelu orin ayo.


2. Fi iyin fun! Jesu, Olurapada wa
 
   Fun wa O t‘eje Re sile Oku

   On ni apata ati reti gbala wa

   Yin Jesu ti a kan m'agbelebu

   Olugbala t'o f’ara da irora nla

   Ti a fi ade egun de lori

   Eniti a pa nitori awa eda

   Oba Ogo njoba titi lailai.


3. Fi iyin fun! Jesu, Olurapada wa

   Ki ariwo iyin gba orun kan

   Jesu Oluwa njoba ati lai lai

   Se l’oba gbogb'enyi alagbara

   Asegun iku, fi yo rohin na ka

   Isegun re ha da, isa‐oku?

   Jesu ye! ko tun si wahala fun wa mo

   Tori O lagbara lati gbala

   Tori O lagbara lati gbala. Amin

English »

Update Hymn