HYMN 105

H.C. 574, 75 (FE 122)
"Anu re duro lailai" - Ps. 136:11. EJE ka f'inu didun

   Yin Oluwa Olore,

   Anu Re o wa titi,

   L’ododo dajudaju.


2. On, nipa agbara Re

   F'imole s'aiye titun

   Anu Re o wa titi,

   L’ododo dajudaju.


3. O mbo awon alaini

   Ati gbogbo alaye

   Anu Re o wa titi,

   L’ododo dajudaju.


4. O mbukun ayanfe Re,

   Li aginji aiye yi

   Anu Re o wa titi,

   L’ododo dajudaju.


5. E je ka f'inu didun

   Yin Oluwa Olore;

   Anu Re o wa titi,

   L’ododo dajudaju. Amin

English »

Update Hymn