HYMN 107

8.7.8.7 D1. GBO orin 'yin dida aye

   T’egberun orile nko

   Orin didun bi t'angeli

   O ndun bi omi pupo

   'Bukun, ogo, ipa gbala

   Fun Olorun lor‘ite

   Baba, Omo, Emi Mimo

   Olola, lainipekun.


2. Titi lo, lat‘oro d‘ale

   Lor‘olukuluku ‘le

   Lat‘ opolopo eniyan

   llu alawo pupa

   ‘Lawo dudu t'a da n’ide

   Funfun ti o po niye

  Omnira alarinkiri

  De ‘le awon Arabu.


3. Lati ebute otutu

   De ile ti o mooru

   Awon olokan gbigbona

   Leba okun Pasifik’

   Lat’opo aimoye okan

   Onigbagbo alayo

   Awon to nsona bibo Re

  Won fere de Sion na.


4. Akojo orile-ede

   Lat’inu eya ahon

   Gbo, won nkorin iyin titi

   Gbo orin ologo ni

   O b’afonifoji mole

   O si ndun lori oke

   O ndun si waju tit‘o fi

   Kun ibugbe Olorun.


5. Gbo, didun orin na dapo

   Mo orin awon t’orun,

   Awon t’o koja n‘nu danwo

   Sinu isimi loke

   Won wo aso ailabawon

   Imo ‘segun lowo won

   Won nfi duru ko Hosana.


6. “Ogo fun Eni t'o fe wa

   T'O we wa n'nu eje Re

   K'oba, alufa, ma korin

   Si Baba, Olorun wa

   K'eeyan mimo on Angeli

   Ko Aleluya titi:

   Asegun orun apadi:

   Olodumare joba." Amin

English »

Update Hymn