HYMN 11

C.M.S 21, H.C 29, t.S 370, 
8s7s (FE 28)
"Eniti npa o mo ki itogbe" - Ps 121:4


1. K’A to sun, Olugbala wa,

   Fun wa n’ibukun ale,

   A jewo ese fun O,

   Iwo lo le gba wa la.


2. B’ile tile ti su dudu 

   Okun ko le se wa mo 

   Iwo eniti ki sare, 

   Nso awon enia Re.


3. B’iparun tile yi wa ka, 

   Ti ofa nfo wa koja 

   Awon Angeli yi wa ka, 

   Awa o wa l‘ailewu.


4. Sugbon b’iku ba ji wa pa, 

   Ti busun wa di iboji

   Je k’ ile mo wa sodo Re, 

   L’ ayo at’ alafia.


5. N’irele awa f’ara wa, 

   Sabe abo Re, Baba 

   Jesu, ‘Wo t’osun bi awa 

   Se orun wa bi Tire.


6. Emi Mimo rado bo wa, 

   Tan 'mole s’okunkun wa, 

   Tit’awa o fi ri ojo 

   Imole aiyeraiye. Amin

English »

Update Hymn