HYMN 110

(FE 127)s
“Yin Oluwa Iwo okan mi”
Tune: E ti gbo orin ile wura na1. GBOGB'omo Egbe Serafu

   Ati Kerubu l‘aiye

   K’e da ‘lu ati ‘jo nyin po

   K’e si yin Oba-Ogo.

Egbe: Yin Oluwa, yin l’egbegbe

      Yin Oluwa lokokan

      Oba mimo l’Olorun

      Yin Oluwa ‘wo okan mi.


2. Larin wahala ati ‘ja

   Larin idekun esu

   Larin isimu at'egan

   Ni Serafu ny’Oluwa.

Egbe: Yin Oluwa, yin...


3. Obangiji Oba mimo

   Ni ‘yin at’ope ye fun

   K’a mu keta gbogbo kuro

   K'a le gb‘ ade irawo.

Egbe: Yin Oluwa, yin...


4. Baba Ogo dariji wa,

   Omo Mimo da wa si,

   Emi Mimo radobo wa,

   K'a si jogun ‘te ogo.

Egbe: Yin Oluwa, yin l’egbegbe

      Yin Oluwa lokokan

      Oba mimo l’Olorun

      Yin Oluwa ‘wo okan mi. Amin

English »

Update Hymn