HYMN 117

H.C. 579, t.H.C. 123, 10s 11s
"Oluwa Olorun mi, Iwo tobi jojo" 
Ps.104:1 (FE 134)


1. E wole f'Oba Ologo julo

   E korin ipa ati ile Re,

   Alabo wa ni‘Eni lgbanis,

   O ngbe anu ogo, Eleru ni iyin.


2. E so t’ipa Re, e so t'ore Re 

   Mole l'aso Re, kobi Re, Orun 

   Ara ti nsan ni keke ‘binu Re je

   Ipa ona Re ni a ko sile mo.


3. Aiye yi pelu ekun yanu re, 

  Olorun, agbara Re l'o da won 

  O fi idi re mule, ko si le yi,

  O si f'okun se aso igunwa Re.


4. Enu ha le so ti itoju Re? 

   Ninu afefe, ninu imole

   Itoju Re wa nin' odo t‘o nsan 

   O si wa ninu iri ati ojo.


5. Awa erupe, aw‘alailera,

   ‘Wo l'a gbekele, O ki o da ni 

   Anu Re ronu, o si le de opin 

   Eleda, Alabo, Olugbala wa


6. ‘Wo Alagbara, Onife julo 

   B‘awon angeli ti nyin O loke

   Be l’awa eda Re, niwon t'a le se, 

   A o ma juba Re, a o ma yin O. Amin

English »

Update Hymn