HYMN 118

C.M.S. 563, S.O. ED D7s (FE 135)
"Iwo ki ise eru mo, Iwo di arole
Olorun nipase Kristi" - Gal. 4:71. EWE ti Oba orun,

   Korin didun be ti nlo 

   Korin ‘yin Olugbala 

   Ologo ‘nu ise Re.

Egbe: A nlo ‘le sodo Olorun 

      Lona t'awon Baba rin 

      Nwon si nyo: nisisiyi 

      Ayo won l'awa o ri.


2. A nlo sodo Olorun 

  Lona t'awon Baba rin 

  Nwon si nyo: nisisiyi, 

  Ayo won l'awa o ri.

Egbe: A nlo ‘le sodo...

3. Korin agbo kekere

   E o simi n'ite Re, 

   ‘Bit'a pese 'joko nyin 

   Ibe si n'ijoba nyin. 

Egbe: A nlo ‘le sodo...


4. W'Oke, omo imole 

   Ilu Sion wa lokan 

   Ibe n‘ile wa titi;

   Ibe l'ao r'Oluwa. 

Egbe: A nlo ‘le sodo...


5. Kerubu, tesiwaju 

   Serafu, ma jafara 

   Kristi Omo Baba nwi 

   Pe laifoiya ka ma lo. 

Egbe: A nlo ‘le sodo...


6. Jesu, a nlo l'ase Re, 

   A ko‘hun gbogbo sile 

   lwo ma j‘ amona wa, 

   A o si ma ba o lo.

Egbe: A nlo ‘le sodo...


7. A f’ogo fun Baba wa, 

   A f'ogo fun Omo Re; 

   Ogo ni f’Emi Mimo, 

   Mu wa de ‘le ayo na.

Egbe: A nlo ‘le sodo Olorun 

      Lona t'awon Baba rin 

      Nwon si nyo: nisisiyi 

      Ayo won l'awa o ri. Amen

English »

Update Hymn