HYMN 119

H.C. 562, C.M. (FE 136)
"On I’Oluwa awon Oluwa, at’Oba
awon oba" - Ifihan 17:141. GBOGBO aiye, gbe Jesu ga, 

   Angeli, e wole fun

   E mu ade Oba Re wa, 

   Se l'Oba awon Oba.


2. E se l’Oba enyin Martyr 

   Ti npe ni pepe Re 

   Gbe gbongbon-igi Jesse ga 

   Se l‘Oba awon oba.


3. Enyin iru-omo Israel 

   Ti a ti rapada

   E ki enit’o gba nyin la, 

   Se l’Oba awon Oba.


4. Gbogbo enia elese

   Ranti ‘banuje nyin

   E te ‘kogun nyin s'ese Re

   Se l'Oba awon oba.


5. Ki gbogbo orile-ede

   Ni gbogbo agbaiye

   Ki nwon ki, “Kabiyesile” 

   Se l’Oba awon oba.


6. A ba le pel'awon t’orun 

   Lati ma juba Re

   K'a ba le jo jumo Korin 

   Se l’Oba awon oba. Amin

English »

Update Hymn