HYMN 121

1. F'ORUK' Olorun loke 

   T’O l'agbara at’ola 

   Olorun ibi gbogbo 

   N'iyin ati ogo wa


2. F‘oruko Krist’ Oluwa 

   Om’ Olorun ti a bi

   Krist’ t’O da ohun gbogbo 

   Ni k'a san ‘yin ailopin.


3. F'Olorun Emi Mimo 

   Ni k’iyin pipe wa lae 

   Pelu baba at’Omo 

   Okan l’oruko, l’ogo.


4. Orin t'a ti ko koja

   T’ao si ma ko lae leyi

   Ki awon iran ti mbo 

   Dapo korin didun na. Amin

English »

Update Hymn