HYMN 122

Tune: CM1. OLORUN Olodumare 

   Baba, Omo, Emi 

   Riri Eni t’a ko le mo 

   Eni t’a ko le ri.


2. Ye! Baba Olodumare 

   K'a wariri fun O

   Ni gbogbo orile-ede 

   Li a o ma sin O.


3. Olorun Omo, Ore wa

   “Wo t'o ra wa pada 

   Ma jowo wa, Olugbala 

   Gba wa patapata.


4. A! Olorun Emi Mimo 

   Wo Olore-Ofe

   A be O, fun wa ni imo

   K’a m’Olorun n’ife.


5. Okansoso sugbon meta 

   Eni Metalokan

   Olorun awamaridi 
 
   Eni Metalokan. Amin

English »

Update Hymn