HYMN 123

H.C. 550, L.M (FE 140)1. GBOGBO enyin ti ngbe aiye 

   E f’ayo korin s'Oluwa 

   F’iberu sin, e yin logo

   E f’ayo wa siwaju Re.


2. Oluwa, On li Olorun

   O da wa laisi ‘ranwo wa 

   Tire l'awa se, O mbo wa; 

  O ntoju wa b'agutan Re.


3. E f‘iyin wo ile Re wa

   E f'ayo sunm’ agbala Re; 

   E yin, e bukun oko Re 

   N’tori be l‘o ye k’a mase.


4. N'tori rere l'Olorun wa

   Anu Re wa bakanna lai, 

  Oto Re ko fi ‘gba kan ye, 

  Oduro lat’iran de ‘ran. Amin

English »

Update Hymn