HYMN 128

S. 492, RM (FE 145)
“E ma lepa eyiti nse rere” - 1Tess. 5:151. OMO Egbe Seraf’ dide 

   Dide lati b’esu jagun 

   Jesu Olugbala segun 

   Sise n’nu ogba Oluwa re. 

Egbe: Sise n'nu ogba Oluwa re, 

      Sise... Sise... Wa,

      Sise ki 'kore to de.


2. Omo Egbe Kerub dide 
 
   Opo Okan lo ti daku

   Opo lo si ti sako lo, 

   Jesu npe nyin, e bo wa ‘le. 

Egbe: Sise n'nu ogba...


3. Aladura ti mura tan

   Lati gbe ogo Jesu ga; 

   B’aje kan ta felefele 

   Maikeli Balogun wa ti de. 

Egbe: Sise n'nu ogba...


4. Joshua sise, o si ye 

   Serafu y‘o sise re ye 

   Elijah sise, o si ye 

   Kerubu y’o sise re ye. 

Egbe: Sise n'nu ogba...


5. Shedrak sise, o si ye, 

   Mesaki sise o si ye, 

   Abednigo se o si ye 

   Serafu yio se l’aseye. 

Egbe: Sise n'nu ogba...


6. Abraham sise, o si ye, 

   Isaaki sise, o si ye, 

   Jakobu sise l’aseye 

   T’Egbe Aladura yio ye. 

Egbe: Sise n'nu ogba...


7. Ope ni fun Olugbala

   To wa s’aye aginju yi

   To bo ogo Re s' apa kan 

   O jiya ka le ri ‘gbala. 

Egbe: Sise n'nu ogba...


8. Kerubu pelu Serafu

   E f'ogo fun baba loke 

   E f'ogo fun Omo Re

   E f'ogo fun Emi Mimo. 

Egbe: Sise n'nu ogba Oluwa re, 

      Sise... Sise... Wa,

      Sise ki 'kore to de. Amin

English »

Update Hymn