HYMN 129

P.B 408 4s (FE 146)1. YIN Olorun Abraham 

   To gunwa lok’orun 

   Eni agba aiyeraiye 

   Olorun ‘fe

   Emi Jehofa nla

   T'aiye t‘orun njewo 

   Mo yin oruko mimo Re 

   Olubukun.


2. B'ipa ara baje
 
   T’aiye t’esu ndena

   Ngo dojuko ile Kenaan, 

   Nip'ase Re. 

   Ngo la ibu koja

   Ngo tejumo Jesu

   Larin aginju to leru 

   Ngo ma rin lo.


3. S'Olorun Oba l‘oke 

   L'olor‘ Angeli nke 

   Wipe Mimo Mimo 

   Olodumare,

   Eniti o ti wa,

   Ti yio si wa lailai, 

   Emi Jehovah Baba nla 

   Kabiyesi. Amin

English »

Update Hymn