HYMN 130

C.M.S. 565, H.C 587 t.H.C. 581 
8s. 7s (FE 147)
"Mo gbonhun nla kan ti opolopo enia
l'orun wipe, Alleluyah" - Ifihan 19:11. ALLELUYAH! orin t’o dun 

   Ohun ayo ti ki ku 

   Alleluyah! orin didun 

   T‘awon t‘o wa l’orun fe 

   N'ile ti Olorun mi ngbe

   Ni nwon nko tosan-toru.


2. Alleluyah! ljo orun

   E le korin ayo na, 

   Alleluyah! orin ‘segun 

   Ye awon t'a rapada 

   Awa ero at‘alejo

   Iyin wa ko nilari.


3. Alleluya! orin ayo

   Lo ye wa nigbagbogbo 

   Alleluya! ohun aro

   Da mo orin ayo wa; 

   Gbat' a wa laiye osi yi, 

   A ngbawe f‘ese wa.


4. Iyin dapo m‘adua wa; 

   Gbo tiwa, Metalokan! 

   Mu wa de 'waju Re I‘ayo 

   K'a r‘Odagutan t‘a pa

   K‘a le ma ko Alleluyah, 

   Nibe lai ati lailai. Amin

English »

Update Hymn