HYMN 132

(FE 149)
“Emi o yin O tinutinu mi gbogbo"
 -Ps.138:1


1. ENYIN Angel orun ebu sayo 

   Kerubu Serafu aiye gberin 

   K’awa ko ke Hosanna

   Ka si foribale fun 

   Metalokan Olore. 

Egbe: Ka jo ho, Ka jo yo 

      Nitori Baba pe wa sinu agbo 

      Ka jo ho, ka jo yo

      Ka si le n'iwa mimo 

      Ti y'o mu wa de Kenaan.


2. A dupe t'Olorun wa pelu wa, 

   A dupe pe Michael je ti wa 

   E je ka jo damuso

   Ka si yin Baba loke

   Ti O da wa si d'oni. 

Egbe: Ka jo ho, Ka jo yo...


3. Oluso-Agutan Israeli,

   lwo ti ki sun, ti ki togbe 

   Masai fi opa Re to 

   Awon to sun ninu wa 

   K‘ife Re ko le ma tan. 

Egbe: Ka jo ho, Ka jo yo...


4. Baba, masai se wa l‘agutan Re, 

   Ti yio ma gbo ipe Oluwa Re, 

   Ma je ka sonu kuro

   Ninu ona toro na

   Ti o lo si ibi iye.

Egbe: Ka jo ho, Ka jo yo...


5. Alabukunfun n'lwo eniti

   O npese fun awon eni igbani 

   Jowo masai be wa wo,

   Pelu ebun rere Re,

   K’awa le sin O dopin.

Egbe: Ka jo ho, Ka jo yo 

      Nitori Baba pe wa sinu agbo 

      Ka jo ho, ka jo yo

      Ka si le n'iwa mimo 

      Ti y'o mu wa de Kenaan. Amin

English »

Update Hymn