HYMN 133

(FE 150)
"Gbe Oluwa ka iwaju re 
nigbagbo" - Ps. 16:81. KO su wa lati ma ko orinti igbani 

   Ogo f'Olorun Aleluya!

   A le fi igbagbo korin na s'oke kikan 

   Ogo f’Olorun, Aleluya!

Egbe: Omo Olorun ni eto lati ma bu s'ayo

      Pe ona yi nye wa si

      Okan wa ns'aferi Re:

      Nigb’o se a o de afin Oba wa ologo

      Ogo f'Olorun, Aleluya!


2. Awa mbe n'nu ibu ife t'o ra wa pada 

  Ogo f'Olorun Aleluya!

  Awa y'o fi iye goke lo s‘oke orun 

  Ogo f‘Olorun, Aleluya!

Egbe: Omo Olorun ni eto...


3. Awa nlo si afin kan ti a fi wura ko 

  Ogo f’Olorun Aleluya!

  Nibiti ao ri Oba ogo n’nu ewa Re 

  Ogo f’Olorun, Aleluya!

Egbe: Omo Olorun ni eto...


4. Nibe ao korin titun t’anu t‘O da 

   wa nde

   Ogo f’Olorun Aleluya!

   Nibe awon ayanfe yo korin ‘yin 

   ti Krist;

   Ogo f’Olorun, Aleluya!

Egbe: Omo Olorun ni eto lati ma bu s'ayo

      Pe ona yi nye wa si

      Okan wa ns'aferi Re:

      Nigb’o se a o de afin Oba wa ologo

      Ogo f'Olorun, Aleluya! Amin

English »

Update Hymn