HYMN 134

Tune: LM1. B’ORUKO Jesu ti dun to

   Ogo ni fun Oruko re

   O tan banuje at’ogbe

   Ogo ni fun Oruko Re.

Egbe: Ogo f’oko Re, Ogo f'oko Re 

      Ogo f'oruko Oluwa

      Ogo f'oko Re, Ogo f'oko Re 

      Ogo f’oruko Oluwa.


2. O wo okan to gb'ogbe san 

   Ogo ni fun oruko Re 

   Onje ni f 'okan t'ebi npa 

   Ogo ni fun oruko Re. 

Egbe: Ogo f’oko Re...


3. O tan aniyan elese 

   Ogo ni fun Oruko re 

   O fun alare ni simi 

   Ogo ni fun oruko re. 

Egbe: Ogo f’oko Re...


4. Nje un o royin na f’elese 

   Ogo ni fun oruko Re

   Pe mo ti ri Olugbala

   Ogo ni fun oruko Re.

Egbe: Ogo f’oko Re, Ogo f'oko Re 

      Ogo f'oruko Oluwa

      Ogo f'oko Re, Ogo f'oko Re 

      Ogo f’oruko Oluwa. Amin

English »

Update Hymn