HYMN 138

(FE 155)
“lba mase pe Oluwa ti o ti wa ni tiwa” 
- Ps. 124:11. lBASE p’Oluwa

   Ko ti wa ni tiwa

   Lo ye k’awa ma wi 

   Nigbat’ese gbogun tiwa. 

Egbe: Ope ni f'Oluwa

      Oba wa Olore

      A ke kabiyesi

      A f'ope fun Jehofa

     T'o gba wa Iowo ota,

     A dupe Oluwu.


2. Nwon ‘ba bo wa mole 

   Pelu agbara won,

   Ope ni f ’Oluwa,

   Ti ko jeki t’esu bori.

Egbe: Ope ni f'Oluwa...


3. Okan wa yo b'eiye 

   Nin' okun apeiye 

   Okun ja, awa yo,

   E yo Jesu da wa sile.

Egbe: Ope ni f'Oluwa...


4. Tire ni Oluwa 

   Lati gbe wa leke 

   Gbogbo awon ota, 

   T'o wu ko tile yi wa ka.

Egbe: Ope ni f'Oluwa...


5. Ara f ’okan bale

   Sodo Olugbala

   B’esu ti gbon to ni,

   Ko to kini kan fun Jesu.

Egbe: Ope ni f'Oluwa...


6. Iranlowo wa mbe 

   L'Oruko Oluwa

   T’O d’orun on aiye 

   Oba awon eni Mimo.

Egbe: Ope ni f'Oluwa...


7. Ogo fun Baba wa,

   Ogo fun Omo Re,

   Ogo f’Emi Mimo 

   Metalokan jo gbo tiwa.

Egbe: Ope ni f'Oluwa

      Oba wa Olore

      A ke kabiyesi

      A f'ope fun Jehofa

     T'o gba wa Iowo ota,

     A dupe Oluwu. Amin

English »

Update Hymn