HYMN 139

(FE 156)
Tune: Children of Jerusalem1. KERUBU e ho f’ayo

   K'a f'ope f‘Olorun wa,

   Fun idasi wa oni,

   Iyin fun Metalokan.

Egbe: E ho ye, Kerubu, e gbe 'rin 

      E ho ye, Serafu, egbe ’rin 

      Halleluyah, Halleluyah,

      Halleluyah, s’Oba wa.


2. Oluwa, gba ore wa 

   Fun ajodun t’oni yi, 

   Ran ‘bukun Re s'ori wa 

   Fun wa ni ayo kikun.

Egbe: E ho ye, Kerubu..


3. Yin Olorun Oba wa, 

   Egbe ohun iyin ga, 

   Fun ife ojojumo 

   Orisun ayo gbogbo. 

Egbe: E ho ye, Kerubu..


4. Fun wa l‘onje ojo wa, 

   At'aso to ye fun wa

   Ki omo Re ma rahun mo 

   Sure fun wa lojo aiye wa. 

Egbe: E ho ye, Kerubu..


5. Enyin Egbe Aladura 

   K’e mura si adura; 

   Orin isegun l'a o ko 

   Lagbara Metalokan, 

Egbe: E ho ye, Kerubu..


6. Jowo Jehovah Mimo 

   M’ese Egbe wa duro 

   Jehovah Nissi Baba 

   K’a le sin O de opin.

Egbe: E ho ye, Kerubu, e gbe 'rin 

      E ho ye, Serafu, egbe ’rin 

      Halleluyah, Halleluyah,

      Halleluyah, s’Oba wa. Amin

English »

Update Hymn