HYMN 140

(FE 157)
"Efi ope fun Oluwa" - Ps. 136:11. OM'Egbe Serafu 

   At’Egbe Kerubu

   E f’ope fun Olorun wa, 

   E f'ope fun Olorun wa 

   T’iru ojo oni.

   Fi soju emi wa. 

Egbe: E ba wa korin po,

      K’awa jumo k'AIleluya 

      Ope to ye fun Jehovah 

      Oba Onibu-Ore.


2. Opo Elegbe wa,

   Ni ko r’ojo oni, 

   Opolopo ti sako lo 

   Idamu wa f’elomiran, 

   Opo si ti koja

   Lo si aiyeraiye.

Egbe: E ba wa korin po...


3. Egbe Aladura,

   E mura si adura;

   Gbe ida ‘segun nyin soke 
  
   Oluwa yio ba wa segun 

   Oto l’esu gbogun

   Ko ni le bori wa.

Egbe: E ba wa korin po...


4. Ninu odun tawa yi

   Agan yio gb’omo pon 

   Awon alaisan yo dide! 

   Arun ko ni ya ile wa, 

   Onirobinuje;

   Yio ri itunu gba.

Egbe: E ba wa korin po...


5. F‘awon ti ko r'ise 

   Baba yio pese
 
   Awon t‘ebi npa yio si yo 

   Awon t'o je ‘gbese y‘o san 

   Aini ko ni si mo

   Ayo yio kari wa. 

Egbe: E ba wa korin po...


6. lfe l'akoja ofin

   Baba fun wa n'ife

   Ki agba feran omode 

   At’okunrin at'obirin, 

   Ife l’awon Angeli

   Fi nyin Baba loke.

Egbe: E ba wa korin po...


7. lwe Woli Joel

   Ni ori ekeji 

   Ese ekejidinlogbon 

   Ase na se si Kerubu 

   Ati Serafu loni,

   Ni arin Egbe wa. 

Egbe: E ba wa korin po...


8. Ogo ni fun Baba

   Ogo ni fun Omo

   Ogo ni fun Emi Mimo 

   Ogo ni f ’Olodumare

   ‘Wo ni Serafu nwo

   Ma je k’oju, ti wa.

Egbe: E ba wa korin po,

      K’awa jumo k'AIleluya 

      Ope to ye fun Jehovah 

      Oba Onibu-Ore. Amin

English »

Update Hymn