HYMN 143

(FE 160)
“Eho iho ayo si Oluwa" - Ps. 100:11. GBOGBO Egbe Onigbagbo 

   T’o wa ni gbogbo aiye 

   T‘awon to wa nigberiko

   Ko jade wa woran.

Egbe: Ka jo ho. Halleluya! 

      F' Oba Olodumare 

      A sope a t'ope da, 

      T'o mu wa dojo oni.


2. Gbogbo Egbe ni gbogbo Ijo,

   Ko si 'ru eyi ri

   Ti Maikieli je Balogun fun 

   Ko s’egbe to dun to. 

Egbe: Ka jo ho...


3. Emi Mimo lo ndari wa, 

   T'enikan ko le mo

   A f’awon t‘a firan na han 

  Lo mo ijinle re.

Egbe: Ka jo ho...


4. At’okunrin at’obinrin, 

   T’o wa ni Serafu 

   Egbe ogun onigbagbo 

   K’a jumo d'orin po. 

Egbe: Ka jo ho...


5. Aje, Oso, ko n’ipa kan 

   Lor'Egbe t’awa yi, 

   Balogun Egbe Serafu 

   Ti jagun o molu.

Egbe: Ka jo ho...


6. Awamaridi n'ise Re 

   T'enikan ko le mo 

   Eda aiye, eda orun 

   Ko le ridi ‘se Re. 

Egbe: Ka jo ho...


7. Gbogbo awon alailera 

   To wa nin ‘Egbe na; 

   Njeri si ohun ti nwon ri, 

   Oluwa lo nsabo won. 

Egbe: Ka jo ho...


8. Awon Egbe to wa lorun 

   Nko si Serafu t‘aiye 

   Pe ka mura ka d'owo po

   Ka jo yin Oba Ogo. 

Egbe: Ka jo ho...


9. Pipe, Mimo, Tito, Rere 

   Fawon to wa lorun 

   Imole itansan si ntan 

   lrawo Owuro.

Egbe: Ka jo ho...


10. Mimo ati Mimo julo 

    Jehovah-Jireh wa, 

    Jehovah‐Rufi yio so wa 

    Latubotan aiye wa.

Egbe: Ka jo ho. Halleluya! 

      F' Oba Olodumare 

      A sope a t'ope da, 

      T'o mu wa dojo oni. Amin

English »

Update Hymn