HYMN 146

(FE 164)
“Eleda re li oko re" - Isaiah 54:51. ELEDA gbogbo aiye

   Li ase Re ni

   Awa pejo loni 

   Lati yin Oko Re. 

Egbe: A dupe Iowo Re 

      Baba Olore,

      Ki 'bukun Re orun 

      Ba le gbogbo wa.


2. Toju wa Baba orun 

   Larin aiye wa yi 

   Pa wa mo k’o bo wa, 

   Pese f’aini wa.

Egbe: A dupe Iowo Re...


3. Kerubu, Serafu

   E m’okan nyin le, 

   Awa ni Baba nla 

   T'o mo edun wa. 

Egbe: A dupe Iowo Re...


4. Kerubu, Serafu 

   E d’amure nyin 

   E ma fi aye sile 

   Fun emi Esu.

Egbe: A dupe Iowo Re...


5. Enyin asaju wa,

   E ku ‘se Emi 

   Olorun alaye

   Yio wa pelu nyin. 

Egbe: A dupe Iowo Re...


6. Enyin Aladura 

   K'e ma gbadura 

   Metalokan y'o gbo 

   Y'o segun fun wa. 

Egbe: A dupe Iowo Re...


7. Gbogbo enyin agan,

   Baba yio pese 

   Enyin ti e bimo 

   Gbogbo won yio la.

Egbe: A dupe Iowo Re...


8. Enyin t'e si loyun

   Jah yio s’abo nyin

   Enyin t'e ko ri se 

   Jah yio pese.

Egbe: A dupe Iowo Re 

      Baba Olore,

      Ki 'bukun Re orun 

      Ba le gbogbo wa. Amin

English »

Update Hymn