HYMN 149

6.6.6.6.8.81. BABA, Eleda wa, 

   Gbo orin iyin wa 

   L’ aye ati l’orun 

   Baba Olubukun: 

   Iwo l’ogo ati iyin 

   Ope, ati ola ye fun.


2. ‘Wo Olorun omo, 

   T’ O ku lati gba wa 

   Eni t’O ji dide

   Ti O si goke lo: 

   Iwo l’ogo, ati iyin 

   Ope, ati ola ye fun.


3. Si O Emi Mimo, 

   Ni a korin iyin 

   Iwo t’o f ’imole 

   Iye si okan wa

   Iwo l’ogo, ati iyin 

   Ope ati ola ye fun.


4. Mimo, mimo, mimo 

   N’iyin Metalokan

   L’ aye ati l’orun 

   L'a o ma korin pe

   Iwo l’ogo, ati iyin 

   Ope ati ola ye fun. Amin

English »

Update Hymn