HYMN 15

C.M.S 20, H.C 22, 10s 4s (FE 32) 
“Li osan pelu o fi awo sanma se amona won,
ati loru gbogbo pelu imole ino" - Ps. 78:14


1. 'WO Imole! larin okun aiye,

   Ma sin mi lo,

   Okunkun su, mo si jina s'ile

   Ma sin mi lo,

   To ‘sise mi: ohun ehin ola

   Emi ko bere, ‘sise Kan to fun mi.


2. Nigbakan ri, emi ko be O, pe 

   Ma sin mi lo,

   Beni nko fe O, sugbon nigbayi, 

   Ma sin mi lo,

   Afe aiye ni mo ti nto lehin, 

  Sugbon Jesu, ma ranti igbani.


3. lpa Re l'o ti ndi mi mu y‘o si 

   Ma sin mi lo,

   Ninu ere ati yangi aiye, 

   Ma sin mi lo,

   Titi em‘o fi ri awon won ni, 

   Ti mo fe, ti nwon ti f'aiye sile.


4. K'o to di ‘gba na, l'ona aiye yi 

   T’iwo ti rin 

   Ma sin mi lo, Jesu Olugbala 

   S’ile Baba

   Ki nle simi lehin ija aiye 

   Ninu imole ti ko nipekun. Amin

English »

Update Hymn