HYMN 151

C.M.S 553, H.C 568 S.M (FE169) 
“Nwon si nko orin Mose, iranse 
Olorun, ati orin Od'agutan" - Ifi. 15:31. JI! ko orin Mose

   At t'Odagutan

   Ji gbogbo okan at‘ahon 

   Ki nwon yin Oluwa.


2. Korin ti iku re,

   Korin ajinde Re, 

   Korin b’o ti mbebe loke 

   F’ese awon t'O ru.


3. Enyin ero l'ona

   E korin b’e ti nlo

   E yo ninu Od’agutan 

   Ninu Kristi Oba.


4. E fe gbo k'O wipe 

   ‘Alabukun, e wa"

   On fere pe nyin lo kuro 

   K’O mu Tire lo ‘le.


5. Nibe l’aokorin 

   lyin Re ailopin

   Orun y’o si gbe ‘rin Mose 

   Ati t’Od‘agutan. Amin

English »

Update Hymn