HYMN 160

O.t. H.C 247, D.S.M (FE 179)
“Nwon si kun fun Emi Mimo" - Ise 2:41. EMI Olorun mi, 

   L‘ojo ‘tewogba yi

   Gege b’ojo Pentikosti 

   Sokale l’agbara 

   Lokan kan l‘apade 

   Ninu ile Re yi

   A duro de ileri Re, 

   A duro de Emi.


2. B’iro iji lile,

   Wa kun ‘nu ile yi

   Mi Oni isokan si wa 

   Okan kan, imo kan,

   Fun ewe at‘agba 

   L‘ogbon at’oke wa
  
   Fi okan gbigbona fun wa 

   K'a yin, k’agbadura.


3. Emi imole wa,

   Le okunkun jade

   Siwaju ni k’imole tan

   Tit’ d’osangangan

   Emi otito wa,

   S’amona wa titi

   Emi Isodomo, si wa 

   S’okan wa di mimo. Amin

English »

Update Hymn