HYMN 164

O.t. H.C 264 D8s. 7s (FE 183)
"Gbogbo nwon si kun fun Emi
Mimo"- Ise 2:41. BABA wa orun, awa de, 

   Awa alailagbara

   Fi Emi Mimo Re kun wa, 

   K’o so gbogbo wa d’otun 

   Wa! Emi Mimo, jare wa! 

   F'ede titun s’okan wa 

   Ebun nla Re ni la ntoro 

   T'ojo nla Pentikosti.


2. Ranti ileri Re, Jesu

   Tu Emi Re s'ara wa,

   Fi alafia Re fun wa, 

   T'aye ko Ie fifun ni

   Wa! Emi Mimo, jare wa! 

   Pa ese run l'okan wa, 

   Ebun nla Re ni l'a ntoro 

   T'ojo nla Pentikosti.


3. Adaba orun! ba le wa,

   Fi agbara Re fun wa;

   Ki gbogbo orile ede

   Teriba f’Olugbala,

   K‘a gburo Re jakejado

   ILe okunkun wa yi 

   Ebun nla Re ni l'a ntoro 

   T’ojo nla Pentikosti. Amin

English »

Update Hymn