HYMN 165

8.7 (FE 184)
“Tani enyin o ha fi Olorun wa?” 
- Ise 40:25



1.  OLUWA Agbara fohun 

     Bi ara loke Sinai

     Awon Angeli gbohun Re, 

     Nwon si gbon fun iberu.


Egbe:  lpe ndun, Angeli ho 

           Halleluya! l’orin won 

           O npada bo ninu ogo 

           Lati wa gba ijoba.


2.  Jesu Oluwa mbo wa, 

     E jade lo pade Re 

     Opo yio kun fun ayo 

     Opo fun ibanuje. 

Egbe:  lpe ndun...


3.  OJO ‘binu, ojo eru

     T'aiye t‘orun yio fo-lo 

     Kini elese yio se

     Le yoju ni ojo na? 

Egbe:  lpe ndun...


4.  Adun aiye ti buse 

     Mura, Egbe Serafu; 

     Olukore fere de, 

     Alikama ni tire. 

Egbe:  lpe ndun...


5.  Mase gbekele aiye 

     Ore aiye a fo lo 

     Enit‘o gb’aiye m‘aiya 

     Y'o gun s’ebute ofo.

Egbe:  lpe ndun...


6.  Oluwa m‘awon Tire 

     O ti se won l’ayanfe 

     Awon ti ko sin Jesu 

    Ni yio jebi nikehin. 

Egbe:  lpe ndun...


7.  ‘Gbat'ipe ‘kehin ba dun 

     Jewo wa Oba Ogo

     Nipa ore-ofe Re

     Ki a le ba O gunwa.

Egbe:  lpe ndun, Angeli ho 

           Halleluya! l’orin won 

           O npada bo ninu ogo 

           Lati wa gba ijoba.  Amin

English »

Update Hymn