HYMN 167

S.522. P.M (FE 185)
Tune: 'Ojo Ibukun yio si ro'
"E fi iyin fun Oluwa" - Ps. 14:11. EDUMARE Jah Jehovah 

   OBA Onibu-Ore

   Mo mu ope mi wa fun O

   Mo wa jewo ore Re.

Egbe: Wa Olugbohun 

      Tewogb'ohun ebe mi

      Baba mo wa d'opo Re mu 

      F'oyin s'aiye fun mi.


2. Edumare Jah Jehovah 

   Re mi lekun laiye mi 

   Mase je ki ota yo mi 

   Gbe mi leke isoro.

Egbe: Wa Olugbohun...


3. Edumare Jah Jehovah 

   Ko s'alabaro fun mi 

   Mo ko aniyan mi to O wa,

   Maje k'aiye ri'di mi.

Egbe: Wa Olugbohun...


4. Edumare Jah Jehovah 

   Fun mi n'ibale okan 

   Mase je ki ile le mi 

   Mase je k'ona na mi.

Egbe: Wa Olugbohun...


5. Edumare Jah Jehovah 

   Jek' awon 'mo wa tunla

   Awon agon nwo O loju

   F'Omo rere jinki won.

Egbe: Wa Olugbohun...


6. Edumare Jah Jehovah 

   Se aiye mi ni rere

   Gba mi lowo oso, aje 

   Ma fi mi t’ore f’Esu. 

Egbe: Wa Olugbohun...


7. Edumare Jah Jehovah, 

   Bukun wa tile-tona

   S'opo at’asa Ijo wa, 

   Bukun wa kari-kari.

Egbe: Wa Olugbohun 

      Tewogb'ohun ebe mi

      Baba mo wa d'opo Re mu 

      F'oyin s'aiye fun mi. Amin

English »

Update Hymn