HYMN 168

1. L’ORI oke Sion t’o ga j‘orun lo 

   N’ilu ‘yanu t’o l‘ewa pupo 

   Nigboose emi si lo si ilu naa 

   Tori mo n to sura mi sibe.

Egbe: Mo n to isura mi si orun I'oke

      N'ilu t’o dara, ilu ewa

      Gba t’a ba r’ogo Re, n o ni ere pupo 

      Tori mo n to sura mi sibe.


2. Mo gbo pe le kan n be f’awon eni mimo 

   Ti Olugbala ti lo pese

   Ita re je wura, at’ opopo wura

   Emi n to isura mi sibe.

Egbe: Mo n to isura mi si...


3. Gbogbo ife okan ati agbara mi 

   At’ise ti mo n se pelu Re

   Wonyi yoo je oro ti n o ri n’ikehin 

   Tori mo n to sura mi sibe.

Egbe: Mo n to isura mi si...


4. Bi mo tile n kiri bi alaini laye 

   N'nu sona at'adura gbogbo

   Laipe n o gbo ipe ayo lati re le 

   Tori mo n to sura mi Sibe.

Egbe: Mo n to isura mi si orun I'oke

      N'ilu t’o dara, ilu ewa

      Gba t’a ba r’ogo Re, n o ni ere pupo 

      Tori mo n to sura mi sibe. Amin

English »

Update Hymn