HYMN 169

S.S. & S417 (FE 187)
Tune: Anu Re Oluwa lawa ntoro 
"Anu Re po de orun" - Ps. 57:101. OLUWA awa omo Re tun de 

   Lati wa anu re.

   Ni ajodun isin Ikore wa, 

   Masai senu fun wa.

Egbe: Anu! Anu! Anu la nfe 

      Iowo Re

      Baba wa orun

      Jo si ferese Orun Re loni 

      Rojo anu le wa.


2. Jesu Oluwa l’ojo aiye Re 

   Oba ‘lanu ni O

   Awon adete ati afoju 

   R'anu gba lowo Re

Egbe: Anu! Anu! Anu...

3. Lodun yi, Oluwa awa mbe o 

   Ma jek' ise won wa

   K’O si je k'a s’owo b’ode p’ade 

   K'ara de gbogbo wa.

Egbe: Anu! Anu! Anu...


4. Mase je ki esu ri wa gbe se 

   Ni gbogb’ ojo aiye wa;

   Ko si ti 'lekun iku at'arun

   Mu wa di amodun.

Egbe: Anu! Anu! Anu...

5. Oluwa, dari ese wa ji wa 

   T’a fi bi O ninu

   Jo se ayipada rere fun wa 

   K‘a le ma je Tire.

Egbe: Anu! Anu! Anu...


6. Nigbat’ikore aiye ba pari 

   T'a ko awa na jo

   B’ikore sinu aba Re orun 

   F’ anu tewogba wa.

Egbe: Anu! Anu! Anu la nfe 

      Iowo Re

      Baba wa orun

      Jo si ferese Orun Re loni 

      Rojo anu le wa. Amin

English »

Update Hymn