HYMN 170

7s (FE 188) 
Tune: Eje ka finu didun 
"Eniti o nfi onje fun eda gbogbo nitori
anu re duro Iailai" - Ps. 136:251. YIN Oluwa Oba ‘wa 

   Egbe ohun iyin ga

   Anu re o titi 

  Lododo dajudaju.


2. Yin Enit’ o da orun 

   Ti o nran l‘ojojumo 

   Anu re o wa titi 

   Lododo dajudaju.


3. Ati osupa l'oru

  Ti o ntanmole jeje 

  Anu re o wa titi 

  Lododo dajudaju.


4. Yin Enit’o nm‘ojo ro, 

   T‘o nmu irugbin dagba 

   Anu re o wa titi 

   Lododo dajudaju.


5. Enit’o pase fun ‘le 

   Lati mu eso po si 

   Anu re o wa titi 

   Lododo dajudaju.


6. Yin fun ikore oko

   O mu ki a ka wa kun; 

   Anu re o wa titi 

   Lododo dajudaju.


7. Yin f‘onje t'o ju yi lo, 

   Eri ‘bukun ailopin 

   Anu re o wa titi 

   Lododo dajudaju.


8. Ogo f 'Oba olore

   Ki gbogbo eda gberin

   Ogo fun Baba, Omo

   At’ Emi: Metalokan. Amin

English »

Update Hymn