HYMN 171

H.C 59 6. 8s (FE 189)
“Nwan nyo niwaju Re gege bi 
ayo ikore" - Ise 9:131.  OLUWA ‘kore, ‘Wole l'a nyin 

lleri Re ‘gbani ko ye

Orisi igba si nyipo,

Ododun kun fun ore Re 

Lojo oni, awa dupe

Jek‘ iyin gba okan wa kan.


2.  B'akoko ‘rugbin mu wa yo 

B'igba erun nmu oru wa; 

‘Gbati owo ojo ba nrinle

Tab'igbat’ikore ba pon 

'Wo Oba wa l'a o ma yin

'Wo l‘alakoso gbogbo won.


3.  Ju gbogbo re lo, nigbati 

Owo Re fun opo ka ‘le

Gba t'ohun ayo, gbilekun 

B'eda ti n ko ire won jo;

Awa pelu y’o ma yin O 

Ore Re ni gbogbo wa npin.


4.  Oluwa ‘kore, Tire ni,

Ojo ti nro orun ti nran

lrugbin ti a gbin sile

Tire l’ohun ti nmu dagba:

Otun l’ebun Re l’ododun 

Otun n’iyin Re l’enu wa.  Amin

English »

Update Hymn