HYMN 173

H.C. 57 D. &s (FE 191)
"Eniti nfi ekun rin lo, ti o si gbe
irugbin Iowo, loto yio fi ayo pada 
wa, yio si ru iti re" - Ps. 126:61. Wa, enyin olope wa, 

   Gbe orin ikore ga

   Ire gbogbo ti wole 

   K'otutu oye to de 

   Olorun Eleda wa 

   L'o ti pese f’aini wa 

   Wa k‘a re ‘le Olorun 

   Gbe orin ikore ga.


2. Oko, Olorun l'aiye 

   Lati s'eso iyin Re 

   Alikama at'epo 

   Ndagba f'aro tab‘ayo 

   Ehu na. ipe tele

   Siri oka nikehin 

   Oluwa ‘kore, mu wa 

   Je eso rere fun O.


3. N’tori Olorun wa mbo 

   Y’o si kore Re s’ile 

  On o gbon gbogbo panti 

  Kuro I’oko Re n’jo na

  Y’o f’ase f’awon Angeli 

  Lati gba epo s’ina

  Lati ko alikama 

  Si aba Re titi lai.


4. Beni, ma wa, Oluwa

   Si ikore ikehin

   Ko awon enia Re jo 

   Kuro l’ese at’ aro

   So won di mimo lailai 

   Ki nwon le ma ba O gbe; 

   Wa t’iwo t’Angeli Re, 

   Gbe orin ikore ga. Amin

English »

Update Hymn