HYMN 174

C.M.S 47 S.522 P.M (FE 192)
“Emi o si jeki ojo ki o ro l'akoko
re, ojo ibukun yio si ro" - Ese.34:261. Ojo ibukun y’o si ro! 

Ileri ife l’eyi

A o ni itura didun 

Lat’odo Olugbala.

Egbe: Ojo Ibukun, Ojo ibukun l’a nfe

      Iri anu nse yi wa ka 

      Sugbon ojo l’a ntoro.


2. ‘Ojo ibukun y’o si ro! 

   Isoji iyebiye

   Lori oke on petele 

   Iro opo ojo mbo.

Egbe: Ojo Ibukun, Ojo ibukun...


3. ‘Ojo ibukun y’o si ro 

   Ran won si wa Oluwa 

   Fun wa ni itura didun 

   Wa, f’ola fun oro Re.

Egbe: Ojo Ibukun, Ojo ibukun...


4. ‘Ojo ibukun y’o si ro 

   lba je le ro loni!

   B’a ti njewo f’Olorun wa 

   T’a npe oruko Jesu.

Egbe: Ojo Ibukun, Ojo ibukun l’a nfe

      Iri anu nse yi wa ka 

      Sugbon ojo l’a ntoro. Amin

English »

Update Hymn