HYMN 178

(FE 196)
Tune: m.r.d.s.d.r.m,
"Kiyesi, O mbo ninu awosanma” - Ifi. 1:71. lWO mbo wa, Oluwa 

   lwo mbo wa, Oba mi 

   Ninu ‘tansan ewa Re

   Ni titayo Ogo re 

   Mura de, mura de.

Egbe: Oko 'yawo f'ere de;

      L'oru ni igbe yio ta,

      Mura l'o ko okan mi.


2. Wundia to s’oloto

   Ti mura nigbagbogbo 

   Igba ayo sunmole

   lgba awe y‘odopin. 

Egbe: Oko 'yawo f'ere de...


3. lwo mbo wa nitoto

   A o pade Re lona

   A o ri O, a mo O,

   Ni ‘dapo mimo julo. 

Egbe: Oko 'yawo f'ere de...


4. Wura ko ni le gba O, 

   Ohun asan l‘oro je 

   lgbagbo ti ko mira

   Ni y'o gb‘ade nikehin.

Egbe: Oko 'yawo f'ere de...


5. Wundia mewa l’a yan 

   Marun pere lo yege 

   Marun ko ni ororo 

   lna emi won ti ku.

Egbe: Oko 'yawo f'ere de...


6. ‘Binu Re tobi pupo

   Si awon t’o gbagbe Re 

   Ewure apa osi

   L’ao se won nikehin 

Egbe: Oko 'yawo f'ere de...


7. Jowo se wa l‘ayanfe,

   Ki a le ba O joba

   Angeli l‘ao ba kegbe

   Ti a o gbe aiku wo.

Egbe: Oko 'yawo f'ere de;

      L'oru ni igbe yio ta,

      Mura l'o ko okan mi. Amin

English »

Update Hymn