HYMN 179

C.M.S. 63 A & M. 50 L.M (FE 197) 
“Emi o si tun pada wa" - John 14:31. LEBA Odo Jordani ni, 

   Onibaptist nke wipe 

   Oluwa mbo! Oluwa mbo! 

   E gbo ‘hin ayo: Oba mbo.


2. K'ese tan ni gbogbo okan 

   K’olorun ba le ba wa gbe 

   K'a pa ile okan wa mo

   Ki Alejo-nla yi to de.


3. Jesu. lwo ni igbala

   Esan ati Alabo wa: 

   B‘itanna l’awa ‘ba segbe 

   Bikose l‘ore-ofe Re.


4. S’awotan awon alaisan 

   Gb’elese to subu dide 

   Tanmole Re ka ‘bi gbogbo 

   Mu ewa aiye bo s’ipo.


5. K’a f’iyin f’Omo Olorun 

   Bibo Eni mu ‘dande wa;

   Enit’ a sin pelu Baba 

   At’Olorun Emi Mimo. Amin

English »

Update Hymn