HYMN 18

C.M.S 16, H.C 21, L.M (FE 35)
“Emi o dubule Ii alafia" - Ps. 4:8


1. IWO imole okan mi,

   Li odo Re oru ko si

   Ki kuku aiye ma bo o,
  
   Kuro I'oju iranse Re.


2. Nigba t'orun ale didun 

   Ba npa ipenpeju mi de 

   K‘ero mi je lati simi 

   Lai l’aiya Olugbala mi.


3. Ba mi gbe l'oro tit'ale 

   Laisi Re emi ko le wa, 

   Ba mi gbe gbat’ile ba nsu 

   Laisi Re, emi ko le ku


4. Bi otosi omo Re kan, 

   Ba tapa s'oro Re loni 

   Oluwa, sise oro Re 

   Ma jek'o sun ninu ese


5. Bukun fun awon alaisan 

   Pese fun awon talaka

   K‘orun alawe l'ale yi 

   Dabi orun omo titun.


6. Sure fun wa nighat’ aji, 

   K'a to m’ohun aiye yi se,

   Titi awa o de bite

   T'a o si de ijoba Re. Amin

English »

Update Hymn