HYMN 180

C.M.S. 71 H.C. 74 P.M (FE 198)
"Igba awon oku de ti a o da won 
l’eja” - Ifi. 11:181. OLORUN, kini mo ri yi! 

   Opin de f’ohun gbogbo 

   Onidajo araiye yo,

   O gunwa n‘ite ‘dajo

   Ipe dun iboji si tu 

   Gbogbo awon oku sile 

   Mura, lo ko, okan mi.


2. Oku n’nu Krist’ y’o ko jinde 

   Nigba ‘pe ‘kehin ba dun 

   Nwon o lo ko, l’awosanma, 

   Nwon o fi ayo yi ka

   Ko s’ eru ti y’o b‘okan won 

   Oju Re da imole bo

   Awon ti o mura de.


3. Sugbon elese t’on t’eru!

   Ni gbigbona ‘binu Re

   Nwon o dide, nwon o si ri, 

   Pe, o se, nwon ko ba mo

   Ojo Ore-Ofe koja 
  
   Nwon ngbon niwaju ‘te ‘dajo’ 

   Awon ti ko mura de.


4. Olorun, kini mo ri yi 
 
   Opin de f'ohun gbobgo!

   Onidajo araiye yo 

   O gunwa n‘ile ‘dajo 

   L‘ese agbelebu mo nwo 

   Gbat’ ohun gbogbo y'o koja

   Bayi ni ngo mura de. Amin

English »

Update Hymn