HYMN 181

(FE 199)
"Emi moo wa, ere mi si mbe pelu
mi" - Ifi. 22:12



1. 'GBA Jesu ba de lati pin ere na,

  B'o j'osan tabi l'oru

  Y' ha ri wa nibi ta gbe nsona 

  Pelu atupa wa ti ntan.

Egbe: A ha le wipe a mura 

      tan-ara

      Lati lo sile didan?

      Yio ha ba wa nibi ta gbe nsona

      Duro titi Oluwa yio fi de.


2. Bi l'owuro li afemojumo

   Ni yio pe wa lokokan,

   'Gba ta f'Oluwa lebun wa pada

   Yio dahun pe O seun.

Egbe: A ha le wipe...


3. Ka s'otito ninu ilana Re 

   Ti sa ipa wa gbogbo;

   Bi okan wa ko ba de wa lebi

   A o n'isimi Ogo.

Egbe: A ha le wipe...


4. Ibukun ni fun awon ti nsona 

   Nwon o pin nin' ogo Re;

   Bi O ba de losan tabi l'oru

   Yo ha ba wa ni isona.

Egbe: A ha le wipe a mura 

      tan-ara

      Lati lo sile didan?

      Yio ha ba wa nibi ta gbe nsona

      Duro titi Oluwa yio fi de. Amin

English »

Update Hymn