HYMN 184

LM E.O 55. C.M.S 62. 6. 6s
"Olurapadaa yio si wa si Sioni"
Isa 59:201. SUNMO odo wa, Emmanuel

   Wa, ra Israeli pada

   T'o nsofo li oko eru

   Titi Jesu y’o tun pada. 

Egbe: E yo eyo! Emmanuel

      Y'o wa s'odo wa Israeli.


2. Wa, Opa alade Jesse 

   K’o gba wa I‘owo ota wa 

   Gba wa low'orun apadi 

   Fun wa ni 'segun l’ori ‘ku.

Egbe: E yo eyo! Emmanuel...


3. Sunmo wa, Wo ila‐orun 

   Ki bibo Re se ‘tunu wa 

   Tu gbogbo isudede ka 

   M’ese ati egbe kuro.

Egbe: E yo eyo! Emmanuel...


4. Wa Omo ‘lekun Dafidi 

   ‘Lekun orun y‘o si fun O: 

   Tun ona orun se fun wa

   Jo se ona osi fun wa. 

Egbe: E yo eyo! Emmanuel...


5. Sunmo wa Oluwa ipa, 

   T‘o f'ofin fun enia Re 

   Nigbani l'ori oke Sinai, 

   ‘Nu eru at'agbara nla.

Egbe: E yo eyo! Emmanuel

      Y'o wa s'odo wa Israeli. Amin

English »

Update Hymn