HYMN 188

C.M.S. 58 H.C. 78 tabi t.H.C 96 
7s. 6s (FE 206)
“Nigbati o di arin oganjo, igbe ta soke
wipe wo o, oko iyawo mbo, e jade 
lo pade Re" - Matt. 25:6
Tune: Stand up, Stand up for Jesus1.  YO enyin onigbagbo

Jeki ‘mole nyin tan 

Igba ale mbo tete 

Oru si fere de,

Oko lyawo dide

O fere sunmole 

Dide, gbadura, sora 

L’oru n‘igbe y’o ta.


2.  E be fitila nyin wo, 

F’ororo sinu won

E duro de ‘gbala nyin 

Ipari ‘se aiye

Awon oluso nwipe 

Oko ‘yawo de tan

E pade re, b‘O ti mbo 

Pelu orin iyin.


3.  Enyin wundia mimo 

Gbe ohun nyin soke 

Titi n'nu orin ayo 

Pelu awon Angel 

Onje iyawo se tan 

‘Lekun na si sile 

Dide, arole ogo

Oko lyawo mbo.


4.  Enyin ti e fi suru 

Ru agbelebu nyin

E o si joha lailai 

‘Gbati ‘ponju ba tan 

Yi ite ogo Re ka

E o r‘ Od'agutan

E o r' ade ogo nyin 

Lele niwaju Re.


5.  Jesu, ‘Wo ireti wa, 

F‘ara Re han fun wa,

'Wo Orun t’a ti nreti 

Ran s'ori ile wa

A gbe owo wa s‘oke

Oluwa je k‘a ri

Ojo ‘rapada aiye

T'o mu wa d'odo Re. Amin

English »

Update Hymn