HYMN 189

C.M.S 61 O.P.M (FE 207)
"Alabukun fun ni enyin ti nforugbin
niha omi gbogbo" - Isa 32:21. ARA mi fun ‘rugbin rere 

   Nigba ifurugbin wa

   Ma sise l'Oruko Jesu 

   Tit’ On o tun pada wa. 

Egbe: Nigbane ni a o f'ayo ka a

      Olukore y'o ko won si aba

      Nigbane ni a o f'ayo ka a

      Olukore y'o ko won si aba.


2. Olugbala pase wipe, 

   Sise nigbat‘o j‘osan 

   Oru mbowa, mura giri 

   Oloko fere de na.

Egbe: Nigbane ni a...


3. T’agba tewe jumo ke, pe, 

   'Wo l'Oluranlowo wa

   Mu ni funrugbin igbagbo

   K'a s’ ero itewogba.

Egbe: Nigbane ni a...


4. Lala ise fere d‘opin
 
   Owo wa fe ba ere

   B'o de ninu olanla Re,

   Yo so fun wa pe, “Siwo” 

Egbe: Nigbane ni a o f'ayo ka a

      Olukore y'o ko won si aba

      Nigbane ni a o f'ayo ka a

      Olukore y'o ko won si aba. Amin

English »

Update Hymn