HYMN 194

C.M.S 59 H.C 109 8s. 7s (FE 212)
“Ife gbogbo orile yio si de” - Hag. 2:71.  WA, Iwo Jesu t’a nreti 

T‘a bi lati da ni n'de 

Gba wa low’ eru at‘ese 

Jek’ ari isimi re.


2.  lwo ni itunu Israel 

Ireti Onigbagbo

Ife gbogbo orile ede 

Ayo okan ti nwona.


3.  Wo t'a bi lati gba wa la, 

Omo ti a bi l’Oba

Ti a bi lati joba lai,

Jeki ijoba re de.


4.  Fi Emi Mimo Re nikan

Se akoso aiya wa

Nipa itoye, kikun Re

Gbe wa s’ori ite Re.  Amin

English »

Update Hymn