HYMN 196

8.7.8.7.8.8.7 & Ref
"O si mu mi goke pelu, lati inu iho
iparun jade wa" - Od. 40:2
1. OKAN wa kun f'ayo loni 

   A ti r‘ona wura na 

  Imole re nta l‘ona wa 

  A ti r’ona wura na

  O ti pe t’ayun Re nyun wa

  Larin ayidayid’ aye

  Die lo ku fun wa k'o bo 

  K'a to r‘ona wura na. 

Egbe: Nje korin, korin ayo 

      F'okan ayo korin soke 

      Imole de, a de ‘ile wa

      Ati r'ona wura na.


2. A pe wa kuro l'aye yi

   A ti r‘ona wura na

  Ore wa gbogbo wa nibe 

  A ti r'ona wura na 

  Awa jeri pe didun na 

  K'a ma tase ijoba orun 

  Pelu Jesu a nlo ‘le wa

  A ti r‘ona wura na.

Egbe: Nje korin, korin ayo...


3. Kiun ni ‘danwo wa t‘o koja 

   A ti t'ona wura na

   Ayo ile mu k’a gbagbe

  A ti r’ona wura na

  ‘Ji kuku ko ni pe kuro 

  lfayabale yoo si de

  A ta ‘gbokun, oko si gun le 

  A ti r’ona wura na.

Egbe: Nje korin, korin ayo...


4. Pel'okan ‘es‘Olorun wa 

   A ti r’ona wura na 

   Lekan ri ti a ti sonu

   A ti r‘ona wura na

   A fe d’odo Olugbala 

  Jesu yoo f'ayo gba wa 

  O je nipa or’ofe nikan 

  A ti r‘ona wura na.

Egbe: Nje korin, korin ayo...5. A dupe low’Olorun wa

  Ti p’a r’ona wura na

  Iyin, ogo ope, ola

  Fun Baba ati Omo

  Ati pelu Emi Mimo

  Metalokan ayeraye

  Titi aye lao ma yin
 
  Pe a r'ona wura na.

Egbe: Ope ni fun O Elshadai 

      Jehofa Rofai ni k’ayin 

      Aleluya orin iyin

      Fun Metalokan soso. Amin

English »

Update Hymn