HYMN 197

S M S M (FE 216)1.  OJO nla kan ma mbo

T'Olusiro y'o de,

Gbogbo eniyan y'o ri

Aye yio wariri.


2.  Igbagbo re ha da

Wo ti ko m'Olorun

T'o f'eda se igbekele

T'o f' Oluwa sile.


3.  Ayo pupo yio wa, 

L'okan ti Jesu ngbe

Ti nwon ti ko aiye sile 

T'o gba Emi Mimo.


4.  E ku 'se Oluwa

Enyin ara at'ore

Ki Baba Olodumare

Bukun fun gbogbo wa.  Amin

English »

Update Hymn