HYMN 199

C.M.S 75 H.C. 846. 10s (FE 218)
"Sa wo o, mo mu ihin rere ayo nla
fun yin wa." - Luku 2:101. JI 'wo Kristian, k‘o ki oro ayo

   Ti a bi Olugbala araye;

   Dide ko korin ife Olorun,

   T'awon Angeli n ko n'ijo kini,

   Lat'odo won n'ihin na ti bere;

   Ihin Om'Olorun t'a bi s'aye.


2. 'Gbana l'a ran akede Angeli;

   T'o so f'awon Olus'aguntan, pe,

   Mo mu 'hinrere Olugbala wa;

   T'a bi fun yin ati gbogbo aye;

   Olorun mu 'leri Re se, loni;

   A bi Olugbala Kristi Oluwa.


3. Bi akede Angel na ti so tan; 

   Opolopo ogun orun si de;

   Nwon nkorin ayo t' eti ko gbo ri, 

   Orun si ho fun yin, Olorun pe, 

   “Ogo ni f'Olorun, l‘oke Orun, 

   Alaafia at’ife s’ enia."


4. O ye k'awa k‘o ma ro l’okan wa,

   lfe nla t’Olorun ni s’araiye,

   K’a si ro t‘omo na t'a bi loni

   T‘o wa jiya oro agbelebu; 

   Ki awa si tele ilana Re; 

   Titi a o fi de ‘bugbe loke.


5. Nigbana ‘gba ba de orun lohun

   Ao korin ayo t'irapada; 

   Ogo enit’ a bi fun wa loni,

   Y’ o maa ran yi wa ka liti Iailai;

   A o ma korin ife Re titi; 

   Oba Angeli, Oba enia. Amin

English »

Update Hymn