HYMN 202

C.M.S.467 H.C.474 8s. 7s. (FE 221)
"Omo na ni Jesu." - Luku 2:431. NIGBA kan ni Betlehemu, 

   lle kekere kan wa;

   Nib‘iya kan te ‘mo re si, 

   Lori ibuje eran;

   Maria n'iya omo na, 

   Jesu Kristi l‘omo na.


2. O t‘orun wa sode aiye, 

   On li Olorun Oluwa, 

   O f' ile eran se ile, 

   ‘Buje eran fun ‘busun; 

   L’odo awon otosi,

   Ni Jesu gbe li aiye.


3. Ni gbogbo igba ewe Re, 

   O gboran o si mb’ola;

   O feran o si nteriba, 

   Fun iya ti ntoju Re;

   O ye ki gbogb’ omode, 

   Ko se olugboran be.


4. 'Tori On je awose wa, 

   A ma dagba bi awa;

  O kere kole dankan se, 

  A ma sokun bi awa;

  O si le ba wa daro, 

  O le ba wa yo pelu.


5. A o f‘oju wa ri nikehin 

   Ni agbara ife Re; 

   Nitori Omo rere yi,

   Ni Oluwa wa l’orun: 

   O nto awa omo Re; 

   S’ona ibiti On lo.


6. Ki se ni ibuje eran,

   Nibiti malu njeun; 

   L‘awa ori l sugbon l’orun, 

   L'owo otun Olorun, 

   'Gba won ‘mo Re B‘irawo, 

   Ba ntan nin’aso ala. Amin

English »

Update Hymn